Ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2024 ilẹ̀ UK: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé - BBC News Yorùbá (2024)

Ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2024 ilẹ̀ UK: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé - BBC News Yorùbá (1)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olootu ijọba ilẹ Britain, Rishi Sunak, ti kede ọjọ kẹrin, oṣu Keje gẹgẹ bi ọjọ ti eto idibo gbogbogbo ọdun 2024 yoo waye nilẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu Conservative party, lo jawe olubori lẹyin eto idibo apapọ to waye loṣu Kejila ọdun 2019 nilẹ UK, ti saa idari rẹ yoo si pari lẹyin ọdun marun un lori aleefa.

Alakalẹ iwe ofin orilẹ ede naa, tọ ka sii pe oṣu Kini ọdun 2025 lo yẹ ki eto idibo apapọ miran tun gberasọ nibẹ.

Ẹkun idibo bii ọtalelẹgbẹta din mẹwaa (650) lo wa nilẹ UK, awọn eeyan lẹkun idibo kọọkan yoo dibo fun aṣoju kan lọ sile igbimọ aṣofin.

Awọn oludije to pọ lo saba maa n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, ṣugbọn awọn mii n da duro laaye ara wọn lati dije fun ipo adari.

Kini idi ti Olootu ijọba UK, Rishi Sunak fi kede eto idibo naa ṣaaju ọjọ?

Ninu awọn eto idibo ọdun 2021 to waye nilẹ Britain, awon eeyan ko fi bẹẹ ṣe atilẹyin fun Rishi Sunak, oludije ẹgbẹ oṣelu Conservative party.

Chris Mason, olootu iroyin nipa ọrọ oṣelu BBC ṣalaye pe, iṣọwọ awọn oloṣelu kan ninu ẹgbe oṣelu naa lero pe, nkan yoo yipada fun ẹgbẹ wọn, leyi to sokunfa sisun eto idibo naa ṣaaju asiko to yẹ ko waye.

Mason sọ pe, “itumọ igbesẹ naa ni, ẹ jẹ ka ṣe eto idibo lasiko yi, tabi ki nnkan gbọna mii yọ.”

Mason tẹsiwaju pe, “Olootu ijọba ọhun lero boya aṣeyori ti jade labẹ idari oun, tabi ko ṣi wa lẹnu ṣisẹ amuṣe rẹ.” Ati wi pe aṣeyori nla ni ti iye owo ọja ba lee ja walẹ, ṣugbọn ti ko sọwọ ijọba nibẹ rara.

Mason fi kun ọrọ rẹ pe, awọn eeyan ilu yoo debi eyikeyi ipenija ọwọngogo owo ori ọja ru ijọba, bẹẹ lo jẹ wi pe inu ikọ aṣejọba yoo dun ti ayipada ba farahan lori ọrọ naa.

Ona lati ṣagbeyẹwo iduro re awọn ẹgbẹ oṣelu ṣaaju eto idibo

Igbesẹ ṣiṣe iwadi nipa ero ọkan awọn eeyan ilu ṣaaju eto idibo, fihan pe oludije ẹgbẹ oṣelu Conservative Party, Rishi Sunak ti gunle ipolongo idibo, ki ẹgbẹ oṣelu alatako Labour party to bẹrẹ ti wọn.

Ẹgbẹ oṣelu labour party, ni ko ri ju ida ogoji ibo nibi awọn eto idibo to ti waye lati ọdun kan sẹyin.

Bakan naa, o jẹyọ pe, ẹgbẹ oṣelu Labour party, yoo bẹrẹ eto ipolongo, nipa bi iwadi erongba awọn eeyan ilu fi lede, bo tilẹ jẹ wi pe igbesẹ naa kii fi bẹẹ sẹnu re nigba mii.

Ẹgbẹ oṣelu Liberal Democrats, to ti figba kan ri jẹ ẹgbẹ to tobi julọ ni orilẹ ede naa, ko ni ida mẹwaa nibi awọn eto idibo naa.

Ireti ẹgbẹ oṣelu ọhun ni lati rọwọmu nibi awọn eto idibo to n bọ lọna.

Kini yoo ṣẹlẹ si iṣẹ akanṣe Rishi Sunak ni Rwanda?

Ṣaaju ni Rishi Sunak ti ṣeleri lati pese oriko kan fun awọn atipo nilẹ Rwanda keto idibo apapọ ilẹ UK to gbera sọ.

O gunle iṣẹ naa lati dena igbesẹ kawọn eeyan maa rin irin ajo ori omi tabi gigun baalu kekeeke wa si ilẹ Europe.

Ẹwẹ, lẹyin to kede eto idibo ṣaaju bo ti yẹ, Sunak sọ pe ilana ọhun yoo bẹrẹ sini fẹsẹ mulẹ ti awọn eeyan ba fibo gbe oun de ipo leekeji, iyẹn lọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2024.

Ẹgbẹ oṣelu Labour party, pinu lati fopin si aṣa dida awọn atipo pada sorilẹ ede wọn, ti ida iṣakoso ba bọ si wọn lọwọ lẹyin eto idibo.

Iṣẹ akanṣe ti ilẹ Rwanda ọhun niwọn ti na ẹgbẹlẹgbẹ millionu owo le lori, bẹẹ lo n fa ariwisi laarin awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji bi ipolongo ibo naa ti n waye.

Awọn wo ni ojulowo oludije?

Ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2024 ilẹ̀ UK: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé - BBC News Yorùbá (2)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oludije latinu ẹgbẹ oṣelu Conservative party, to n tukọ ilẹ naa lọwọ, ati akẹgbẹ rẹ labẹ ẹgbẹ Labour party, ni ti ireti wa pe yoo ni ibo to pọ julọ nibi agbekalẹ eto idibo naa.

Olootu ijọba ilẹ UK, Rishi Sunak, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) ni adari ẹgbẹ oṣelu Conservative party.

O jẹ ọmọ bibi ilẹ Britain ati India akọkọ ti yoo bọ sipo naa, Oun ni olootu ijọba tọjọ ori rẹ kere julọ ninu iwe itan.

Sir Keir Starmer, ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61) lo n lewaju ẹgbẹ oṣelu Labour party, wọn dibo fun un gẹgẹbi adari ẹgbẹ oṣelu naa lọdun 2020, lẹyin saa Jeremy Corbyn, o si jẹ adajọ agba tẹlẹri.

Kini yoo ṣẹlẹ si ile igbimọ aṣofin atawọn aṣofin keto idibo to waye?

Ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2024 ilẹ̀ UK: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé - BBC News Yorùbá (3)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olootu ijọba ilẹ UK ti sọ pe ki Ọba ilẹ Geesi tuleka fun ile igbimọ aṣofin naa, ki eto idibo to gberasọ, igbesẹ naa si waye lọgbọnjọ oṣu karun un.

Awọn aṣofin ọhun ko lagbara lati ṣe ohunkohun mọ, eyikeyi to ba nifẹ lati tẹsiwaju lori ipo rẹ nile igbimọ aṣofin apapọ naa, yoo gbe apoti idibo leekeji.

Awọn aṣofin to le ni ọgọrun ti pinu lati maṣe pada dije mọ ninu awọn eto idibo mii.

Bakan naa, bi eto idibo ba ti ku dẹdẹ ko waye nilẹ UK, awọn minisita ati adari ibẹ ko lẹtọ lati ṣe ohunkohun rara nigba ti ipolongo ba n lọ lọwọ.

Kini yoo wa ṣẹlẹ lẹyin ikede esi idibo naa?

Lẹyin ibo kika, Ọba yoo kede adari ẹgbẹ oṣelu to ni iye ibo to pọ julọ gẹgẹbi olootu lati ṣagbekalẹ iṣejọba tuntun.

Olori ẹgbẹ oṣelu to gbe nipo keji nibi eto idibo naa, yoo duro gẹgẹbi adari ẹgbẹ alatako.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ko ni lagbara lati buwọlu iwe ofin, iyẹn ti awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ba ni iye ibo kan na.

Nidi eyi, Ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ yoo kora jọpọ lati ṣagbekalẹ ijọba pẹlu ẹgbẹ oṣelu miran, tabi ki wọn duro ni ipele keji ninu iṣejọba, ati rireti ibo latọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu yooku, ki wọn to fọwọsi iwe ofin naa.

Ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2024 ilẹ̀ UK: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé - BBC News Yorùbá (2024)
Top Articles
Latest Posts
Article information

Author: Prof. An Powlowski

Last Updated:

Views: 6153

Rating: 4.3 / 5 (64 voted)

Reviews: 95% of readers found this page helpful

Author information

Name: Prof. An Powlowski

Birthday: 1992-09-29

Address: Apt. 994 8891 Orval Hill, Brittnyburgh, AZ 41023-0398

Phone: +26417467956738

Job: District Marketing Strategist

Hobby: Embroidery, Bodybuilding, Motor sports, Amateur radio, Wood carving, Whittling, Air sports

Introduction: My name is Prof. An Powlowski, I am a charming, helpful, attractive, good, graceful, thoughtful, vast person who loves writing and wants to share my knowledge and understanding with you.